Author: Sabine Baring-Gould ; Anonymous Appears in 1 hymnal Lyrics: 1 L’owuro ojo ajinde,
T’ara t’okan y’o pade,
Ekun, ’kanu on irora
Y’o dopin.
2 Nihin won ko le sai pinya
Ki ara ba le sinmi,
K’o si fi idakeroro
Sun fonfon.
3 Fun ’gba die ara are yi
L’a gbe s’ibi ’simi re;
Titi di imole oro
Ajinde.
4 Okan to kanu nisisiyi
To si ngbadura kikan,
Y’o bu s’orin ayo l’ojo
Ajinde.
5 Ara at’okan y’o dapo
Ipinya ko ni si mo
Nwon o ji l’aworan Kristi
Ni’Telorun.
6 A! ewa na at’ayo na
Y’o ti po to l’Ajinde!
Y’o duro, b’orun at’aiye
Ba fo lo.
7 L’oro ojo ajinde wa
’Boji y’o m’ oku re wa;
Baba, iya, omo, ara
Yo pade.
8 Si’dapo ti ofun bayi
Jesu masai ka wa ye
N’nu ku, dajo ka le ro
M’Agbelebu. Used With Tune: MELTON
L'owuro Ojo Ajinde